Ẹ káàbọ̀ sí ètò ẹ̀kọ́ “Ìgbésí-ayé Jésù”! Wo ìgbésí-ayé Jésù láti inú ìwé Ìhìn Rere ti Luku, nínú fíìmù tó ní iye wíwò jùlọ nínú ìtàn-akọọlẹ̀ àgbáyé. Àwọn ẹ̀kọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ló wà, ọkọọkan pẹ̀lú àgẹ̀kúrù ṣókí ti fíìmù náà, tí àwọn ìbéèrè sì tẹ̀lé. Ìwọ yóò ní olùkọ́ tirẹ̀ tí yóò máa fún ọ ní èsì sí àwọn ìdáhùn rẹ, àti pé ìwọ pẹ̀lú lè béèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ. Olùkọ́ni rẹ yóò máa dáhùn sí àwọn ẹ̀kọ́ rẹ ní àárín wákàtí mẹ́rìnlélógójì sí méjìdínlógójì (24–48 hours).
A gba ọ níyànjú láti ma ka ju ẹ̀kọ́ kan tàbí méjì ní ọjọ́ kan. Èyí yóò fún ọ ní àkókò láti ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ń kọ́ ọ, àti láti ní ìbáṣepọ̀ tó jinlẹ̀ pẹ̀lú olùkọ́ rẹ láti jíròrò nípa àwọn ìbéèrè rẹ àti ìgbésí-ayé ìgbàgbọ́ rẹ. Yóò dára púpọ̀ nígbà tí o bá lè lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan láti parí ètò ẹ̀kọ́ kan. Nítorí náà, a tún ń retí pé ìwọ fúnra rẹ ni yóò kọ gbogbo ohun tí o bá fi ránṣẹ́ gẹgẹ bi ìdáhùn, láìlò ẹ̀rọ AI tabíi ChatGPT.
A nireti pé ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú ètò ẹ̀kọ́ yìí, àti pé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti súnmọ́ Ọlọ́run sí i síi!