Eyi je eto eko ti o ni eko merundinlogun (15 lessons) ninu. Yoo fi àwọn ohun ipilẹ̀ṣ ninu Bibeli han ọ, ọrọ Olorun si ọ.
Gbogbo ẹ̀kọ́ ni awon ibeere to tele e. Iwọ yoo ni Olùkọ́ aladani ti yóò fun ọ ni esi lori awon idahun rẹ ati pe iwọ pelu le beere awon ibeere miran lọwọ olùkọ́ re. Oluko re yoo fesi si ẹkọ re ránṣẹ́ laarin wakati mejidinlogbon si omejidinlaadota (24-48 hours). Ni opin eto ẹkọ yii, iwọ yoo gba iwe eri bi oluko rẹ ba ni itelorun pelu bi o se gbìyànjú sí.
A gba ọ ni niyanju lati ka eko kan tabi meji ni ọjọ kan. Eyi yoo fun ọ ni akoko lati ronu jinlẹ̀ lori àwọn ohun ti eko kọọkan n kọ ọ, ati lati ni ibasepo to jinle pelu oluko re lati sọrọ nipa awon ibeere re ati igbesi aye ìgbàgbọ́ rẹ. Yoo dára púpò nigba ti o ba le lo ọṣẹ melokan lati pari eto ẹkọ kan. Nitorina, a tun n reti pe ìwọ funra rẹ ni yoo kọ gbogbo ohun ti o ba fi ránṣẹ́, laisi lilo ẹ̀rọ AI bii ChatGPT.
A nireti pe iwọ yoo ni ayọ ninu eto ẹkọ yii, ati pe yoo ran ọ lọ́wọ́ lati sunmọ Ọlọrun siwaju sii!
Akeko kan nipa eto eko yii sọ pé:
“Ohun to ran mi lọwọ ju ninu eto ẹkọ yii ni igba ti olùkọ́ mi ran mi lọwọ nípa didahun àwọn ibeere mi, mo si ni oye ti o jinlẹ̀ sii. Inu mi dun gan-an fun eyi.”